Sandy Dennis
Sandy Dennis | |
---|---|
Fáìlì:Sandy Dennis.jpg | |
Ọjọ́ìbí | Sandra Dale Dennis Oṣù Kẹrin 27, 1937 Hastings, Nebraska, U.S. |
Aláìsí | March 2, 1992 Westport, Connecticut, U.S. | (ọmọ ọdún 54)
Iṣẹ́ | Actress |
Ìgbà iṣẹ́ | 1956–1991 |
Alábàálòpọ̀ | Gerry Mulligan (1965–1974) Eric Roberts (1980–1985) |
Sandra Dale Dennis (Oṣù kẹrin ọjọ́ kẹta-dín-lọ́gbọ̀n, ọdún 1937 sí Oṣù kẹta ọjọ́ kejì, ọdún 1992) jẹ́ òṣèré obìnrin ti Ilẹ̀ Amẹ́ríkà. Ó ṣe àṣeyọrí nínú fíìmù tó gbé e jáde, "Splendor in the Grass" (ọdún 1961). Fún iṣẹ́ rẹ̀ nínú fíìmù eré dírámà àpanilẹ́rìn-ín "Who's Afraid of Virginia Woolf?" (ọdún 1966), ó gba ẹ̀bùn àmì ẹ̀yẹ fún òṣèré àtìlẹ́yìn obìnrin tó dára jùlọ.
Dennis farahàn nínú àwọn fíìmù wọ̀nyí : The Three Sisters (ọdún 1966), Up the Down Staircase (ọdún 1967), That Cold Day in the Park (ọdún 1969), The Out-of-Towners (ọdún 1970), God Told Me To (ọdún 1976), The Four Seasons (ọdún 1981), Come Back to the Five and Dime, Jimmy Dean (ọdún 1982), àti Another Woman (ọdún 1988). Fíìmù tó farahàn gbẹ̀yìn wá ní dírámà adágún "The Indian Runner" (ọdún 1991).
Dennis ní iṣẹ́ àṣeyọrí nínú iṣẹ́ rẹ̀ lórí ìtàgé, ìfarahàn ṣíṣe eré ìtàgé gangan ti "Come Back to the Five and Dime, Jimmy Dean. Fún iṣẹ́ rẹ̀ nínú jara"A Thousand Clowns, ó gba ẹ̀bùn àmì ẹ̀yẹ Tony fún òṣèré obìnrin tó farahàn tó dára jùlọ. Fún iṣẹ́ rẹ̀ nínú eré"Any Wednesday", ó gba ẹ̀bùn àmì ẹ̀yẹ Tony fún òṣèré obìnrin tó dára jùlọ nínú eré náà
Ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ Ayé Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Wọ́n bí Dennis ní Hastings, Nebraska, ọmọ Yvonne (née Hudson), tó jẹ́ èyí tí àwọn òyìnbó ń pè ní "Secretary", pẹ̀lú Jack Dennis, èyí tí àwọn òyìnbó máa ń pè ní "Postal clerk".[1][2] Ó ní ẹ̀gbọ́n ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Frank. Dennis dàgbà ní Kenesaw, Nebraska, àti Lincoln Nebraska, tí ó jáde láti Ilé-ìwé gíga Lincoln High School ní ọdún 1955; ọ̀kan nínú àwọn ọmọ tí wọ́n jọ wà ní kíláàsì jẹ́ akọ̀wé pẹ̀lú apanilẹ́rìn-ín, Dick Cavett.[3] Ó lọ sí Fásìtì Nebraska Wesleyan àti Fásìtì ti Nebraska, fífarahàn nínú ẹgbẹ́ ìtàgé Lincoln kí ó tó di pé ó kó lọ New York ní ọjọ́ orí ọ̀kàn-dín-lógún.[4] Ó kọ́ eré ṣíṣe ní HB Studio[5] ní Ilẹ̀ New York.
Ikú Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Sandy Dennis kú nípasẹ̀ àìsàn ara kan tí òyìnbó ń pè ní "ovarian cancer" ní oṣù kẹta ọjọ́ kejì, ọdún 1992, ní ilé rẹ̀ ní Westport, Connecticut, ní ọjọ́ orí ẹ̀rìn-lé-láàdọ́ta.[6]
Àwọn Iṣẹ́ Rẹ̀
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Fíìmù
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Tẹlifísàn
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]Year | Title | Role | Notes |
---|---|---|---|
1956 | Guiding Light | Alice Holden | Unknown episodes |
1962 | Naked City | Eleanor Ann Hubber | Episode: "Idylls of a Running Back" |
1963 | Naked City | Lorraine | Episode: "Carrier" |
The Fugitive | Cassie Bolin | Episode: "The Other Side of the Mountain" | |
1964 | Arrest and Trial | Molly White | Episode: "Somewhat Lower Than the Angels" |
Mr. Broadway | Patricia Kelsey | Episode: "Don't Mention My Name in Sheboygan" | |
1968 | A Hatful of Rain | Celia Pope | Television film |
1970 | Only Way Out Is Dead | Dr. Enid Bingham | Television film |
1972 | Something Evil | Marjorie Worden | Television film |
1978 | Police Story | Sharon Bristol | Episode: "Day of Terror... Night of Fear" |
Perfect Gentlemen | Sophie Rosenman | Television film | |
1980 | Wilson's Reward | Martha James | Television film |
1985 | The Execution | Elsa Spahn | Television film |
The Love Boat | Gina Caldwell | Episode: "Roommates/Heartbreakers/Out of the Blue" | |
Alfred Hitchcock Presents | Helen | Episode: "Arthur, or the Gigolo" | |
Young People's Specials | Patricia Benson | Episode: "The Trouble with Mother" | |
1986 | The Equalizer | Kay Wesley | Episode: "Out of the Past" |
Àwọn Ìtọ́ka Sí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Peter Shelley (8 November 2013). Sandy Dennis: The Life and Films. McFarland. ISBN 978-1-4766-0589-0. https://books.google.com/books?id=fd-xAQAAQBAJ&pg=PA1955.
- ↑ "The Hour - Google News Archive Search".
- ↑ Lincoln High School (1955). The Links, vol. 39. Lincoln, NE: Lincoln High School. p. 38.
- ↑ Sandy Dennis. Yahoo Movies.
- ↑ HB Studio Alumni
- ↑ Daniels, Lee A. "Sandy Dennis, Veteran Actress And Prize Winner, Is Dead at 54" The New York Times, March 5, 1992