Biafra
|
Biafra tí a mọ̀ sí orílẹ̀-èdè Biafra[2] jẹ́ ìlú tó yapa kúrò nínú Apá Ìwọ̀-oòrùn Áfíríkà tí ó gba òmìnira ní Nàìjíríà láàárín ọdún 1967 títí di ọdún 1970[3][4] . Àwọn ẹ̀yà Ìgbò ní apá ìlà oòrùn Nàìjíríà ni wọ́n kún bẹ̀ fọ́fọ́fọ́. Ọgbọ́n ọjọ́, Oṣù Èbìbí ọdún 1967 ni ológun àti Gómìnà ẹkùn ìlà oòrùn C. Odumegwu Ojukwu dá Biafra sílẹ̀, lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ làásìgbò ẹlẹ́yà Ẹtà àti ìdìtẹ̀gbàjọba lẹ́yìn òmìnira orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1960 tí èyí sì yọrísí ìpakúpa àwọn Ìgbò àti àwọn ẹ̀yà mìíràn tí wọ́n ń gbé ní àríwá orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ọdún 1966. Lẹ́hìn náà ni àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè Nàìjíríà kógun ja Biafra lẹ́hìn ìyapa, èyí ṣokùnfàfà ìbẹ̀rẹ̀ ogun abẹ́lé orílẹ̀-èdè Nàìjíríà.
Àwọn ìlú bí Haiti, Ivory Coast, Tanzania àti Zambia ni wọ́n rí Biafra bí orílẹ̀-èdè tó kẹ́sẹ járí ṣùgbọ́n àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí kò mọ̀ wọ́n lábẹ́ òfin pèsè ìrànwọ́ ọlọ́gbọ́n ìṣèlú àgbà tàbí ajẹmọ́ ológun fún Biafra, lára wọn ni France, Spain, Portugal, Norway, Israel, Rhodesia, South Africa àti Vatican City.[5] Biafra gba ìrànwọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn àjọ tí kò rọ̀gbọ̀ lé ìjọba, lára wọn ni Joint Church Aid, àwọn ajaguntà ilẹ̀ òkèèrè, Holy Ghost Fathers of Ireland, bẹ́ẹ̀ sì ni pẹ̀lú ìdarí wọn Caritas Internationals àti àwọn ètò ìrànwọ́ Àgùdá tí U. S, bákan náà ni ìdásílẹ̀ San Frontieres wáyé gẹ́gẹ́bí èsì sí ìyà náà.
Àwọn ìtọ́kasí
[àtúnṣe | àtúnṣe àmìọ̀rọ̀]- ↑ Minahan, James (2002). Encyclopedia of the Stateless Nations: S-Z. Greenwood Publishing Group. p. 762. ISBN 0-313-32384-4. http://books.google.com/?id=K94wQ9MF2JsC&pg=PA762.
- ↑ "The Republic of Biafra | AHA". www.historians.org. Retrieved 2022-06-09.
- ↑ "Republic of Biafra (1967-1970) •" (in Èdè Gẹ̀ẹ́sì). 2009-06-21. Retrieved 2022-11-09.
- ↑ Anglin, Douglas G. (1971). "Zambia and the Recognition of Biafra". The African Review: A Journal of African Politics, Development and International Affairs 1 (2): 102–136. ISSN 0856-0056. JSTOR 45341498. https://www.jstor.org/stable/45341498.
- ↑ Lewis, Peter (2007). Oil, Politics, and Economic Change in Indonesia and Nigeria. University of Michigan Press. p. 78. ISBN 9780472024742. "setting in motion a chain of social conflicts that culminated in the attempted secession of Igbo nationalists in 1967"