Májẹ̀mú Láéláé

Lát'ọwọ́ Wikipedia, ìwé ìmọ̀ ọ̀fẹ́
The printable version is no longer supported and may have rendering errors. Please update your browser bookmarks and please use the default browser print function instead.
Àwòrán tó ń ṣàfihàn májẹ̀mú láéláé.

Májẹ̀mú Láéláé je apa kinni ninu Bibeli Mimo, tí ó ní ìwé ọkàn dín logoji, tí wón kó ni èdè Hébérù. Apá kejì Bíbélì mímọ́ ni májẹ̀mú tuntun, èyí tí a ko ni èdè Griki, tí ó sì jẹ́ àkójọ ìwé metadinlogbon.

Májẹ̀mú láéláé jẹ́ akojopo orísi àwọn ìwé tí orisi àwọn ènìyàn mímọ́ ko ni ọpọlọpọ ọdún sẹ́yìn..[1]

Àwọn Kristẹni pín majẹmu Láéláé sí merin: àkókò ni ìwé marun àkókò; àwọn ìwé tí ó sọ nípa ìtàn àwọn ọmọ Israeli, láti ìṣẹ́gun wọn ní Canani sí ìgbà tí a kọ Bábílónì lẹ́ru; àwọn ìwé ọgbọ́n àti ewì àti àwọn ìwé nípa àwọn wòlíì májẹ̀mú Láéláé.

Májẹ̀mú láéláé jẹ́ àkójọ ìwé ọkàn dín logoji, bí ó tilè jẹ́ wípé ìwé Májẹ̀mú Láéláé tí àwọn ìjọ míràn bí ìjọ Kátólíìkì ń lò ní ìwé tí ó tó merindinladota.

Itokasi

  1. Lim, Timothy H. (2005). The Dead Sea Scrolls: A Very Short Introduction. Oxford: Oxford University Press. p. 41.